Fun awa ti a si ranti yoruba ti won ko wa ni ilewe alakobere,eleyi je okan laara ohun ti o nshi wa lori ti a ba ka ni igba yen,e je ka fi ko awon omo wa na.E je ki a fin awon ohun yoruba towulo yi lo awon omo wa leti,aye ti ndi nkan miran,ki apada si ese aro.Eyin je itumo re ni ede geest ti ojogbon Quansy Salako se fun awon omo wa oke okun.

ISÉ NI ÒÒGÙN ÌSÉ........Work is the antidote for poverty
MÚRA SÍ ISÉ RE ÒRÉÈ MI.......Work hard, my friend
ISÉ NI A FI Í DI ENI GIGA.......work is used to elevate one in respect and importance (Aspiring to higher height is fully dependent on hard work)
BÍ A KÒ BÁ RÉNI FÈYÌN TÌ, BÍ ÒLE LÀ Á RÍ;......if we do not have anyone to lean on, we appear indolent
BÍ A KO RÉNI GBÉKÈLÉ,.....if we do not have anyone to trust (we can depend on...)
À A TERA MÓ ISÉ ENI.....we simply work harder
ÌYÁ RE LÈ LÓWÓ LÓWÓ.....your mother may be wealthy
BÀBÁ SÌ LÈ LÉSIN LÉÈKÀN.....your father may have a ranch full of horses
BÍ O BÁ GBÓJÚ LÉ WON,........ if you depend on their riches alone
O TÉ TÁN NI MO SO FÚN O,......you may end up in disgrace, I tell you
OHUN TÍ A KÒ BA JÌYÀ FÚN,.....whatever gain one does not work hard to earn
KÌ Í LÈ TÓJÓ.....usually does not last
OHUN TÍ A BÁ FARA SISÉ FÚN,....whatever gain one works hard to earn
NÍ Í PÉ LÓWÓ ENI.....is the one that lasts in one's hands (while in ones possession)
APÁ LARÁ, ÌGÙNPÁ NÌYEKAN...... the arm is a relative, the elbow is a sibling
BÍ AYÉ N FÉ O LÓNÌÍ,....you may be loved by all today
BÍ O BÁ LÓWÓ LÓWÓ,......it is when you have money
NI WON Á MÁA FÉ O LÓLA......that they will love you tomorrow
TÀBÍ TÍ O BÁ WÀ NÍ IPÒ ÀTÀTÀ,.....or when you are in a high position
AYÉ Á YÉ O SÍ TÈRÍN-TÈRÍN,.....all will honor you with cheers and smiles
JÉ KÍ O DI ENI N RÁÁGÓ,....wait till you become poor or are struggling to get by
KÍ O RÍ BÁYÉ TI Í SÍMÚ SÍ O......and you will see how all grimace at you as they pass you by ÈKÓ SÌ TÚN N SONI Í DÒGÁ,.....education also elevates one in position
MÚRA KÍ O KÓ O DÁRADÁRA.....work hard to acquire good education
BÍ O SÌ RÍ ÒPÒ ÈNÌYÀN,.....and if you see a lot of people
TÍ WÓN N FI ÈKÓ SE ÈRÍN RÍN,....making education a laughing stock
DÁKUN MÁ SE FARA WÉ WON.....please do not emulate or keep their company
ÌYÀ N BÒ FÓMO TÍ KÒ GBÓN,.....suffering is lying in wait for an unserious kid
EKÚN N BE FÓMO TÓ N SÁ KIRI.......sorrow is in the reserve for a truant kid
MÁ FÒWÚRÒ SERÉ, ÒRÉÈ MI,.....do not play with your early years, my friend
MÚRA SÍSÉ, OJÓ N LO.....work harder, time and tide wait for no one.
Let’s pass it on to our children.


Oro ilu naijaria ti wa ti a wo ma le so.Kini a se fe pe ti olori orile ilu America ti o wa si ilu adu la wo fun igba akoko ni igba ti o de ori oye ti o je pe orile ede Ghana ni o lo.Awa nijaria ni igbagbo pe ilu wa ni o tobi julo ni ilu adu lawo sugbon sibesibe,ilu miran lo lo.

Kini ki a ti pe eleyi,nje ko se pe oro wa ti di nkan miran bayi? ape ra wa ni olori sugbon ko ja si nkankan bayi.Oro wa ti di hun bayi,kini ki a se?Lehin odun kan din ni adota,ako ti mo ohun ti a nse.
Eyin omo ilu olorire yin,e ba wa da soro yin,kinni ka a la se si ilo seyin to de ba orile ede yin?

O ga o,asiko ko duro de enikan.
Aye nlo a nto,igbawo lamu odun 2009 ti a di de idaji re
A pele ti akorin ilumoka ni-Micheal Jackson
Oluwa yoo dun awon ebi re ninu
Oro orilede wa yin ko ye ni mo
Eni rogbodiyan idibo,ola awon alajadula,kini a o ti se gbogbo eleyi si
Eyin otokulu ilu e ma wo wa niran
Awon iran bi ran wa yoo be re pe bawo lasese
Oro wa fe atunto nilu yi
Nibo lati si rin
E ba wa da soro yin

Sai Baba


Are Yar Adua ti yo oloselu nla ni,Ogbeni Kingibe kuru ninu ijoba re leyin to de laati ilu okeere.Ahunye hunye orisirisi loti lo nipa yiyo ara kunrin yin nitoripe Are ni o duro ti sai baba nigba ti o fe yan si ipo na nigbati egbe re ko jale lati fowosi yiyan re.Sugbon tinu ko ba gbo sunukun,inu ki baaje,awon esun lorisiri risi ni a ngbo pe o fa isele yin.A gbo pe o se inu meji pelu re ati pe oun lo koko gbe ipolongo iku re nipa ti o wa ni ile iwosan ni ilu okere ti ariwo fi ta.Se e le yi yio wa je ifaseyin fun ogbeni yi ni abi adaba tun ra mu loro re?

Oro di hun bayi o,nipa ailera olori orilede wa.Nje yio wa le se eto ilu bayi?Gbogbo wa la mo bi arun jejere se ma ndanu eniyan,atipe ise takun takun ni e ti yio se olori ma nse,o si gbodo wa ni alafia.Se ki se pe atun bo ninu ikan bo si omiran bayi?.Iyalenu lo je pe bi olorun ti bukun orilede yi to,a ko le to ilu wa daradara.Olori la je ninu iwo orun dusu sugbon gbogbo ihunwa si wa ko fi han rara,a kan je olori lasan ni,a ko le gbe adiye.Kinni ka se si?

Ipinnu

Mo se ileri pe emi yio ma se deede ni gbagede yin lati wakaati yin lo.Ede yoruba je ede kan ti a ko gbodo gbagbe,nitoripe a ni orisun ati pe ipa awon babalawa ko gbodo pee.Asa ati ise yoruba ko gbodo paare,yoruba a gbe wa o.E ku ilu yi,e ku bi gbogbo e se nlo,edumare o ni je ko baaje lori ti wa bi o se baaje loori awon babanla wa.

Eku odun titun

Eyin omo iya mi lorigun merin agbaye mo ki yin pe eku ojo pipe,a si ku odun titun.Igba odun odun kan ni,ajinde ara yio ma je.A ku bi ilu wa ti nlo yin,awon baba nla wa ko ni je ki ilu baje lori wa.E jowo bawo lese ri bi oro atiyan awon alakoso wa miran yin se nlo ati pe kilode ti awa alawo dudu se ri bi a se ri yi,ka yan oselu wa se di rogbodiyan ti o ba ilu bayi?oro na wa ti oju sumi bayi,ki ni e ro pe oro yin yio jasi?Se ki ogbeni Atiku gba kadara re ni abi ki o ta ku pe oun ko gba,e wo ni ti are wa ti o ni ogbeni na ko le de be?

Awon oloselu alatako PDP,AC ti mu Atiku jejebi asoju won ninu idibo apapo.Ako gbodo gbagbe pe Atiku si je omo egbe PDP titi ti egbe miran fi yan,nitooto won ko ri tire ro mo ni PDP sugbon oun na fe mu eyin dani ni ida kan ,ki o si tun je nipa keji. E je eleyin ko ni di rogbodiyan miran bayi ,ti a ba tele ofin ilu wa.Ogbeni yi na owon re si egbe miran nigba ti o ri pe won ko ni fun oun laye ninu egbe na.Olorun ni yio ko wa yo ninu gbogbo wahala ati yan are yin,Se Atiku wa ni o wa kan bayi pelu gbogbo ohun ti a ti po nipa bi won se na owo orilede wa

Iyalenu lo je lati ri pe ogbeni Yar Adua ni o gbe igba oroke ninu idibo fun eni ti yio pe asia PDP fun Are.Lotito ogbeni yin ni gomina ile re-Katsina sugbon ije o ni oye ati imo lati se akoso ilu nla wa yin ati pe nje o ti se igbaradi fun ipo nla yin,ti a ba ranti pe ko pe ti o pinu pe owu fe lo fun ipo na.O da ibi ti won bawa de,a o ti

Nje gbogbo rogbo diyan ti o nlo lari Atiku ati Are yi ko ni ja si nkan miran bayi,nitori oro ti di-kaka ki eku maje sese afi se awa danu lari won.O ti wa han wayi pe awon oloselu ko ri ti mekunnu ro rara,ti ara won ni won ba kiri,ti ko ba je be kini o fa ija a ja doju bo le ti won nba ara won ja yin.O da ni loju pe epe ni awon odo ti o nbo leyin yio ma fi ranse si won,nitori pe won ti ba le je.E wo bi won se so ohun ini orilede wa di ti ebi won,itan won ko le pare ninu iwe itan fun awon iwa o ba ye je ti won se ati pe elese ko ni lo lai jiya bope boya ,ewon won wa ni para de won lojo iwaju ti a ma ni olori gidi ti o fi ife mekunnu se ohun saaju ninu oro re.

Iru iwa wo ni won fe fisile de awa odo ti a nbo leyin,nigba to je pa iwa reere kan kosi lowo won ti a le fi se arikogbo ni tito orilede.O se ni laanu ibi ti a ba orileede wa de yin,nitori pe olori laje ni ile afrika ati pe awa la dabi awo kose fun orile pupo ni iwo orun afika,sugbon ati sora wa di di igba ikole ni oju won,a di ohun a mu se awada.Nje ko ye ka ronu si oro wa bayi?

Nje iwa itini loju ko ni eyi ti oloriwa are obasanjo ati igbakeji re yi nja? won ko ra won sita bi omo ijo mejo.O se ni laanu pe orilede wa ko kuro ni oju kanna lehin odun ogoji le mefa,ti asi tu wa ninu ki a ma so ijoba di oye ile awon kan ati pe owo ilu di ti awon iwoba eniyan kan.Oro yi buru ko ni afiwe nitori pe ko daani loju pe awon oselu wa ni ife awa mekunu ninu raara.Bawo ni oun ti o je ti gbogbo ilu se wa di oun ti a fun omo,ebi ati ale awon oselu,awon omomo won yio si sepe fun won lojo iwaju.Kini eyin eniyan ri si isele yin?

Awon oniwe iroyin se bebe lori oro arabirin Anita Hogan.Nje o ye ki enikeni gbe iru aworan yi sita rara,ki se asa tiwa ni ki a ma se awon iwa palapala wonyi.Se Anita ni ka bawi ni pe o ya aworan yi pelu ololufe re abi awon onibaje oniwe iroyin?e da soro yin

Nje ki se pe aye nlo si opin bayi?e ko ri oun ti awon onise ibi fe se ni ilu geesi ni ose yin,afi ki oluwa maa so wa.E mi ko ro pe olorun ran enikeni lati ma ja ija iparun ti won nse yin.Tobaje pe ki se akisesi ti awon otelemuye se ni,eleyi ko ni a o ma wi.Kini ero pe orilede America abi Geesi le se lati dawo duro awon onija ipa yin ati pe se ilu kankan wa ti o roju nisiyin?


Sebi yoruba lo so pe bi ogiri ko lanu alangba ko le wobe,bi o ba je pe awa se oselu bi won ti se ni agbaye ni ati pe bi o ba o pa, boo ba bulese ti a nbe ka,awon kan yio ma wa ku enikeji won nitori alefa.Iku ogbeni williams yin ko ma gbodo di bi won se so ti ologbe Ige di.Awon agbofinro ko gbodo yo enikeni sile nitori pe,ibikibi ni iku re le ti wa,ki won mase daa duro si PDP nitori AD naa je alatako egbe ree ati pe nigba aye re-oju won ki koo.Kini irisi yin lori oro yin?

Eyin omo kaaro ojire,e ma je ki a gbagbe asa wa nitori pe a fe ma se bi oyinbo.Sebi omo onibi niran ni awa se,kilo wa de ti afe je ki asa wa paarun.Mo lo ri ore mi kan ni Hackney ni aro yin,nigba ti awon omo re jade simi,won kan nawo simi ati pe hello anti ni won se.Mo koo leese kese pe,emi ki se anti won nitori pe egbe iya won ni emi ati pe awon omo mi ju okankan won lo-ki won dobale ki mi bi ogidi omo yooruba-nigba ti awa ndagba gbogbo e ni ti o baju mama wa lo mama ni. Mo ri pe inu won ko dun simi titi ti mo fi lo sugbon mo ti se temi bi omo kaaro ojire.Mama won rerin muse,o si sope o dara to je emi ni mo so fun won,nitori awon ti gbiyanju titi ki won le mo kikini ni tile wa sugbon won ko gbo.

Kini e ri si eyi?

Yoruba is the first language of approximately 30 million West Africans, and is spoken by populations in Southwestern Nigeria, Togo, Benin, and Sierra Leone. Based on the number of people for whom Yoruba is the first language, the political, cultural, and social importance of the language within Africa, and United States national interests tied to economic and diplomatic relations with Yoruba-speaking areas, Yoruba was recognized among the Less Commonly Taught languages as a first priority language by a national panel of language teachers.

Students cite many reasons for studying Yoruba, including personal interest in West African cultures, research interests, and fulfillment of foreign language requirements. African-American students often study Yoruba out of interest in their own heritage, since many of the slaves brought to North America during the 18th and 19th centuries came from Yoruba-speaking areas.

Copyright © 2000 The Board of Regents of the University of Wisconsin System


Eyin eniyan ilu mi,kini e ri si isele ti o nsele si awon oloselu ilu wa nitori ibo ti o nbo lona.A ko ti mu odun 2007 won ti npa ara won bayi,nje eleyi boju mu to.Se ka dori alefa wa to ki a ma para eni,eleyi su mi pupo.Kini e yi eniyan ri si,e je ka gbo?

Mo fi towon towon ki eyin omo kaaro ojire ni gbogbo ayika aye,pe yio sanwa sowo,omo ati alafia.E mi omo yin ajike ni mo ni ki ama bara wa soro ni gbagede yi,ki a si ma fi iku luku lori oro ti o nsele si arin awa omo oduduwa ati pe bawo la se le se ra wa lokan,ki o ri lede wa le dara.E mi ni ipapo pe olukuluku wa ni ipa ti a le ko lati ri pe orilede wa nilosiwaju,ki a ma duro de awon oselu ti won kan ma tanwa lati ri ibo.Kini iba ti iwo fe ko?

Newer Posts Home