Nje gbogbo rogbo diyan ti o nlo lari Atiku ati Are yi ko ni ja si nkan miran bayi,nitori oro ti di-kaka ki eku maje sese afi se awa danu lari won.O ti wa han wayi pe awon oloselu ko ri ti mekunnu ro rara,ti ara won ni won ba kiri,ti ko ba je be kini o fa ija a ja doju bo le ti won nba ara won ja yin.O da ni loju pe epe ni awon odo ti o nbo leyin yio ma fi ranse si won,nitori pe won ti ba le je.E wo bi won se so ohun ini orilede wa di ti ebi won,itan won ko le pare ninu iwe itan fun awon iwa o ba ye je ti won se ati pe elese ko ni lo lai jiya bope boya ,ewon won wa ni para de won lojo iwaju ti a ma ni olori gidi ti o fi ife mekunnu se ohun saaju ninu oro re.

Iru iwa wo ni won fe fisile de awa odo ti a nbo leyin,nigba to je pa iwa reere kan kosi lowo won ti a le fi se arikogbo ni tito orilede.O se ni laanu ibi ti a ba orileede wa de yin,nitori pe olori laje ni ile afrika ati pe awa la dabi awo kose fun orile pupo ni iwo orun afika,sugbon ati sora wa di di igba ikole ni oju won,a di ohun a mu se awada.Nje ko ye ka ronu si oro wa bayi?

0 comments:

Newer Post Older Post Home