Ikini ni ile yoruba

Eyin omo kaaro ojire,e ma je ki a gbagbe asa wa nitori pe a fe ma se bi oyinbo.Sebi omo onibi niran ni awa se,kilo wa de ti afe je ki asa wa paarun.Mo lo ri ore mi kan ni Hackney ni aro yin,nigba ti awon omo re jade simi,won kan nawo simi ati pe hello anti ni won se.Mo koo leese kese pe,emi ki se anti won nitori pe egbe iya won ni emi ati pe awon omo mi ju okankan won lo-ki won dobale ki mi bi ogidi omo yooruba-nigba ti awa ndagba gbogbo e ni ti o baju mama wa lo mama ni. Mo ri pe inu won ko dun simi titi ti mo fi lo sugbon mo ti se temi bi omo kaaro ojire.Mama won rerin muse,o si sope o dara to je emi ni mo so fun won,nitori awon ti gbiyanju titi ki won le mo kikini ni tile wa sugbon won ko gbo.

Kini e ri si eyi?

1 comments:

Awa Yoruba feran lati ma ki awon eniyan. Kiki se patiki ninu asa ibile wa. Pu po ninu awon omo Yoruba ti won gbe ilu oyinbo ni won mo bi won se ki yan. Owo awa obi wan lo ku si lati to won.

3:50 PM  

Newer Post Older Post Home