E ku deede asiko

A ku ipalemo odun,odun yo ba wa layo ati alafia.Odun rere ni yo je fun olukuluku wa,ilu wa aroju araye.Iran yoruba ko ni paarun.Hu hu,kini ka se bi gbogbo re se nlo bayin.Oro ilu wa nfe adura gidigidi,e je ka pawopo jo pa.

Kila tun le se,a ko le ma wo bayi,kini ka se?

1 comments:

Anti Alajikẹ, ẹku asiko yi. Ẹ jẹ ki nlo anfaani gbagede yin lati sọrọ nipa ohun ti o ndun mi lọkan nipa ọrọ ina ẹlẹtiriki orile-ede wa.
Ọrọ ina mọnamọna orile-ede Naijiria to nṣe mọnamọna ntoju su mi. Ọrọ naa ko ye mi rara. Ni akoko yi ti ọpọlọpọ orile-ede ngbe nkan meremere kan tabi omiran ṣe. Awọn eniyan orile-ede ede wa ṣi nlo atupa bi awọn eniyan ti oju wọn ṣi dudu. Awọn eniyan ni orile Amẹrika nlọ sinu osupa, a wa joko l’oju kanna. A ko ri ohun kankan ṣe si ọrọ ina mọnamọna wa ti o ndaku ti o ndaji bi oni warapa.
O ti le ni ọgọrun ọdun ti ina mọnamọna ti duro ni awọn orile-ede bii Amerika, Ile Gẹẹsi ati bẹẹ bẹẹ lọ. Ina mọnamọna ti orile-ede Gusu Afrika npese (South Africa) ju eyiti ti awọn ara ilu won tilẹ nilo lọ. Eyiti o tumọ si wipe, wọn npese ina ni ọpọ yanturu. Orile-ede Ghana ti o wa ni tosi wa ni ilẹ adulawọ naa ṣe ajọdun ọdun melo kan ti ina wọn ti duro ti a wa ko si ri nkankan ṣe si ọrọ ina ti wa. Ko da mi loju wipe a le ibi kan ti a ti le f’ọwọsọya wipe ina mọnamọna wa duro fun odidi ọsẹ kan lai ṣẹju.
A ni epo rọbi, a ni gaasi ti a njo danu ati ọpọlọpọ oorun, sibẹsibẹ a ko ni ina mọnamọna. Ẹrọ amunawa (generator) lo gbode kan, bi o ba yi si bi, ariwo ẹrọ amunawa ni, bi o ba yi si ọhun ariwo ẹ naa tun ni. Bawo ni orile-ede yoo ti ṣe ma lo awọn ẹrọ amunawa yii lati tukọ ọrọ aje rẹ ti yoo si yege? Boya bi ijọba ba fi ofin de kiko awọn ẹrọ amunawa yi wọ orile-ede wa, boya ina mọnamọna wa yoo duro. Ohun ti nko mọ ni bi wọn yoo ni ọkan lati ṣe eyi.
Ẹyin ijọba wa, ẹ jọwọ, ẹ jẹ ki imọlẹ ki o wa, ki o si duro, ki ilọsiwaju le baa de ba orile-ede wa.

9:44 AM  

Older Post Home