O ga o,asiko ko duro de enikan.
Aye nlo a nto,igbawo lamu odun 2009 ti a di de idaji re
A pele ti akorin ilumoka ni-Micheal Jackson
Oluwa yoo dun awon ebi re ninu
Oro orilede wa yin ko ye ni mo
Eni rogbodiyan idibo,ola awon alajadula,kini a o ti se gbogbo eleyi si
Eyin otokulu ilu e ma wo wa niran
Awon iran bi ran wa yoo be re pe bawo lasese
Oro wa fe atunto nilu yi
Nibo lati si rin
E ba wa da soro yin

2 comments:

Arabinrin Ajike,

Oro ni e soo. Sugbon amunkun eru re wo, ni oro naa, o da bi wipe oke ni a n wo a ko wo isale. Oro Naijiria ti wo lati ibere pepe(d:d). Looto awon oselu ba pupo je nibe, sugbon awa ara ilu naa n ko? Die ninu wa lo dara. Fun bi apeere eniyan melo ni e mo(d) ti e le fi inu tan?

Ni temi mo lero wipe ti opolopo ninu wa ba lee pinu wipe ohun ti a ko ni gba awa naa ko ni fi lo(r) elomiran, laipe lai jina oro orile-ede wa a loju.

Ohun edun lo je wipe awon olori elesin ti won ni anfaani lati ba opolopo eniyan soro ko lo anfaani naa daradara. Kaka ki won o fi ye awon omoleyin won wipe opolopo idaamu ti o nba wa, wipe afowofa ara wa ni, n se ni won a maa so fun won wipe aje(d:m) tabi oso(r:m) kan ni o wa ni koro(d:d) ti n ba won ja.

Ju gbogbo re lo, mo lero wipe oro Naijira ti fee ni ojutuu(r:m:d:m), nitori wipe iya(d:d) ti o n je opolopo waa n je ki a maa ronu. Arojinle(d:d:r:d) si ni ipile ilosiwaju eda.

Mo duro bayi naa. Ire o!

5:28 AM  

E se gan ti e ba wa da soro yin,odua a gbe wa,ilu yi o ni baaje.

1:15 AM  

Newer Post Older Post Home