Fun awa ti a si ranti yoruba ti won ko wa ni ilewe alakobere,eleyi je okan laara ohun ti o nshi wa lori ti a ba ka ni igba yen,e je ka fi ko awon omo wa na.E je ki a fin awon ohun yoruba towulo yi lo awon omo wa leti,aye ti ndi nkan miran,ki apada si ese aro.Eyin je itumo re ni ede geest ti ojogbon Quansy Salako se fun awon omo wa oke okun.

ISÉ NI ÒÒGÙN ÌSÉ........Work is the antidote for poverty
MÚRA SÍ ISÉ RE ÒRÉÈ MI.......Work hard, my friend
ISÉ NI A FI Í DI ENI GIGA.......work is used to elevate one in respect and importance (Aspiring to higher height is fully dependent on hard work)
BÍ A KÒ BÁ RÉNI FÈYÌN TÌ, BÍ ÒLE LÀ Á RÍ;......if we do not have anyone to lean on, we appear indolent
BÍ A KO RÉNI GBÉKÈLÉ,.....if we do not have anyone to trust (we can depend on...)
À A TERA MÓ ISÉ ENI.....we simply work harder
ÌYÁ RE LÈ LÓWÓ LÓWÓ.....your mother may be wealthy
BÀBÁ SÌ LÈ LÉSIN LÉÈKÀN.....your father may have a ranch full of horses
BÍ O BÁ GBÓJÚ LÉ WON,........ if you depend on their riches alone
O TÉ TÁN NI MO SO FÚN O,......you may end up in disgrace, I tell you
OHUN TÍ A KÒ BA JÌYÀ FÚN,.....whatever gain one does not work hard to earn
KÌ Í LÈ TÓJÓ.....usually does not last
OHUN TÍ A BÁ FARA SISÉ FÚN,....whatever gain one works hard to earn
NÍ Í PÉ LÓWÓ ENI.....is the one that lasts in one's hands (while in ones possession)
APÁ LARÁ, ÌGÙNPÁ NÌYEKAN...... the arm is a relative, the elbow is a sibling
BÍ AYÉ N FÉ O LÓNÌÍ,....you may be loved by all today
BÍ O BÁ LÓWÓ LÓWÓ,......it is when you have money
NI WON Á MÁA FÉ O LÓLA......that they will love you tomorrow
TÀBÍ TÍ O BÁ WÀ NÍ IPÒ ÀTÀTÀ,.....or when you are in a high position
AYÉ Á YÉ O SÍ TÈRÍN-TÈRÍN,.....all will honor you with cheers and smiles
JÉ KÍ O DI ENI N RÁÁGÓ,....wait till you become poor or are struggling to get by
KÍ O RÍ BÁYÉ TI Í SÍMÚ SÍ O......and you will see how all grimace at you as they pass you by ÈKÓ SÌ TÚN N SONI Í DÒGÁ,.....education also elevates one in position
MÚRA KÍ O KÓ O DÁRADÁRA.....work hard to acquire good education
BÍ O SÌ RÍ ÒPÒ ÈNÌYÀN,.....and if you see a lot of people
TÍ WÓN N FI ÈKÓ SE ÈRÍN RÍN,....making education a laughing stock
DÁKUN MÁ SE FARA WÉ WON.....please do not emulate or keep their company
ÌYÀ N BÒ FÓMO TÍ KÒ GBÓN,.....suffering is lying in wait for an unserious kid
EKÚN N BE FÓMO TÓ N SÁ KIRI.......sorrow is in the reserve for a truant kid
MÁ FÒWÚRÒ SERÉ, ÒRÉÈ MI,.....do not play with your early years, my friend
MÚRA SÍSÉ, OJÓ N LO.....work harder, time and tide wait for no one.
Let’s pass it on to our children.

Newer Posts Older Posts Home