Awon oniwe iroyin se bebe lori oro arabirin Anita Hogan.Nje o ye ki enikeni gbe iru aworan yi sita rara,ki se asa tiwa ni ki a ma se awon iwa palapala wonyi.Se Anita ni ka bawi ni pe o ya aworan yi pelu ololufe re abi awon onibaje oniwe iroyin?e da soro yin

Nje ki se pe aye nlo si opin bayi?e ko ri oun ti awon onise ibi fe se ni ilu geesi ni ose yin,afi ki oluwa maa so wa.E mi ko ro pe olorun ran enikeni lati ma ja ija iparun ti won nse yin.Tobaje pe ki se akisesi ti awon otelemuye se ni,eleyi ko ni a o ma wi.Kini ero pe orilede America abi Geesi le se lati dawo duro awon onija ipa yin ati pe se ilu kankan wa ti o roju nisiyin?


Sebi yoruba lo so pe bi ogiri ko lanu alangba ko le wobe,bi o ba je pe awa se oselu bi won ti se ni agbaye ni ati pe bi o ba o pa, boo ba bulese ti a nbe ka,awon kan yio ma wa ku enikeji won nitori alefa.Iku ogbeni williams yin ko ma gbodo di bi won se so ti ologbe Ige di.Awon agbofinro ko gbodo yo enikeni sile nitori pe,ibikibi ni iku re le ti wa,ki won mase daa duro si PDP nitori AD naa je alatako egbe ree ati pe nigba aye re-oju won ki koo.Kini irisi yin lori oro yin?

Eyin omo kaaro ojire,e ma je ki a gbagbe asa wa nitori pe a fe ma se bi oyinbo.Sebi omo onibi niran ni awa se,kilo wa de ti afe je ki asa wa paarun.Mo lo ri ore mi kan ni Hackney ni aro yin,nigba ti awon omo re jade simi,won kan nawo simi ati pe hello anti ni won se.Mo koo leese kese pe,emi ki se anti won nitori pe egbe iya won ni emi ati pe awon omo mi ju okankan won lo-ki won dobale ki mi bi ogidi omo yooruba-nigba ti awa ndagba gbogbo e ni ti o baju mama wa lo mama ni. Mo ri pe inu won ko dun simi titi ti mo fi lo sugbon mo ti se temi bi omo kaaro ojire.Mama won rerin muse,o si sope o dara to je emi ni mo so fun won,nitori awon ti gbiyanju titi ki won le mo kikini ni tile wa sugbon won ko gbo.

Kini e ri si eyi?

Yoruba is the first language of approximately 30 million West Africans, and is spoken by populations in Southwestern Nigeria, Togo, Benin, and Sierra Leone. Based on the number of people for whom Yoruba is the first language, the political, cultural, and social importance of the language within Africa, and United States national interests tied to economic and diplomatic relations with Yoruba-speaking areas, Yoruba was recognized among the Less Commonly Taught languages as a first priority language by a national panel of language teachers.

Students cite many reasons for studying Yoruba, including personal interest in West African cultures, research interests, and fulfillment of foreign language requirements. African-American students often study Yoruba out of interest in their own heritage, since many of the slaves brought to North America during the 18th and 19th centuries came from Yoruba-speaking areas.

Copyright © 2000 The Board of Regents of the University of Wisconsin System


Eyin eniyan ilu mi,kini e ri si isele ti o nsele si awon oloselu ilu wa nitori ibo ti o nbo lona.A ko ti mu odun 2007 won ti npa ara won bayi,nje eleyi boju mu to.Se ka dori alefa wa to ki a ma para eni,eleyi su mi pupo.Kini e yi eniyan ri si,e je ka gbo?

Mo fi towon towon ki eyin omo kaaro ojire ni gbogbo ayika aye,pe yio sanwa sowo,omo ati alafia.E mi omo yin ajike ni mo ni ki ama bara wa soro ni gbagede yi,ki a si ma fi iku luku lori oro ti o nsele si arin awa omo oduduwa ati pe bawo la se le se ra wa lokan,ki o ri lede wa le dara.E mi ni ipapo pe olukuluku wa ni ipa ti a le ko lati ri pe orilede wa nilosiwaju,ki a ma duro de awon oselu ti won kan ma tanwa lati ri ibo.Kini iba ti iwo fe ko?

Newer Posts Home